1 Ó sàn kí èèyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.
2 Kò dára láti ní ìtara láì ní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì sìnà.
3 Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;ṣíbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.
4 Ọrọ̀ má a ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;ṣùgbọ̀n ọ̀rẹ́ ẹ talákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
5 Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láì jìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
6 Ọ̀pọ̀ ń wá ojú rere Olórí;gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.
7 Gbogbo ará ilé e talákà ni ó pa á tìmélòómélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,kò tilẹ̀ rí wọn rárá.
8 Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
9 Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyàẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.
10 Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọlá ńlá,mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jọba lórí ọmọ aládé.
11 Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù;fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.
12 Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún,ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
13 Aláìgbọ́n ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀sọ̀ọ̀rọ̀ òjò.
14 A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbíṣùgbọ́n aya olóye láti ọdọ̀ Olúwa ni.
15 Ọ̀lẹ ṣíṣẹ́ máa ń fa oorun sísùn fọnfọnfọnebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
16 Ẹni-kẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
17 Ẹni tí ó ṣáànú talákà, Olúwa ní ó yáyóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
18 Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú iparun un rẹ̀.
19 Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀bí ìwọ bá gbàá là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan síi.
20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
21 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyànṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.
22 Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;ó sàn láti jẹ́ talákà ju òpùrọ́ lọ.
23 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá:nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láì sí ewu.
24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
25 Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ síi.
26 Ẹni tí ó já baba rẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jádeó jẹ́ adójútini ọmọ.
27 Yéé tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ tí í mú ni ṣìnà ọmọ mi,ìwọ kì yóò sì sìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìmọ̀.
28 Ajẹ́rìí tí ó bàjẹ́ máa ń kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mi.
29 A ti pèṣè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;àti pàṣán fún ẹ̀yìn aláìgbọ́n.