Òwe 21 BMY

1 Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa;a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.

2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn.

3 Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nàó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ.

4 Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga,ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!

5 Ètè àwọn olóye já sí èrèbí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.

6 Ìṣúra tí a kójọ nípaṣẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹkùn ikú.

7 Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ,nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.

8 Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.

9 Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùléju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.

10 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibialádùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

11 Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n.

12 Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburúó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.

Ìṣúra Ẹni Tí Ó Gbọ́n

13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,òun tìkárarẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.

14 Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:àti owó-àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,dẹ́kun ìbínú líle.

15 Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́:ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

16 Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye,yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.

17 Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di talákà:ẹni tí ó fẹ́ ọtí-wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.

18 Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó-ìràpadà fún olódodo,àti olùrékọjá fún ẹni dídúró-ṣinṣin.

19 Ó sàn láti jókòó ní ihà ju pẹ̀lúoníjà obìnrin àti òṣónú lọ.

20 Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;ṣùgbọ́n ènìyàn aṣiwèrè (òmùgọ̀) jẹ ẹ́ run.

21 Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,òdodo, àti ọlá.

22 Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,ó sì bi ibi-gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.

23 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.

24 Agbéraga àti alágídí ènìyàan ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀,tí ń hùwà nínú àdábọwọ́ ìgbéraga.

25 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé;nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.

26 Ó ń fi ìlara ṣojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́:ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.

27 Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni:mélòómélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà-ibi?

28 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé:ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró.

29 Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le:ṣùgbọ́n ẹni ìdúró-ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

30 Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye,tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa.

31 A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun:ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31