20 Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìṣimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn.
21 Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá.
22 Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn?
23 Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìṣinmi ní alẹ́. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú.
24 Ènìyàn kò le è ṣe ohun kóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run.
25 Nítorí wí pé láìsí Ọlọ́run, ta ni ó le è jẹ tàbí ki o rí ìgbádùn?
26 Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ni ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹlẹ́ṣẹ̀, o fún-un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun-ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí o tẹ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, aṣán ni, ó dàbí ẹni a gbìyànjú àti mú.