1 Àsìkò wà fún ohun gbogboàti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run.
2 Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú,ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.
3 Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú lára dáìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́.
4 Ìgbà láti ṣunkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rínìgbà láti sọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó
5 Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọìgbà láti ṣún mọ́ àti ìgbà láti fà ṣẹ́yìn
6 Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiriìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,
7 Ìgbà láti ya àti ìgbà láti ránìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti ṣọ̀rọ̀