11 Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, ṣíbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.
12 Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láàyè.
13 Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́.
14 Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni.
15 Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀,ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀,Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀
16 Mo sì tún rí ohun mìíràn níabẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,òdodo ni ó wà ní bẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ní o wà ní bẹ̀.
17 Mo rò nínú ọkàn mi,“Ọlọ́run yóò mú ṣẹ sí ìdájọ́Olótìítọ́ pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀,Nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,àti àsìkò fún gbogbo ìṣe.”