5 Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọìgbà láti ṣún mọ́ àti ìgbà láti fà ṣẹ́yìn
6 Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiriìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,
7 Ìgbà láti ya àti ìgbà láti ránìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti ṣọ̀rọ̀
8 Ìgbà láti níìfẹ́ àti ìgbà láti kóríraìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.
9 Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀?
10 Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn.
11 Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, ṣíbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.