1 Orúkọ rere ṣàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ
2 Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ju ibi àṣènítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyànkí alààyè ní èyí ní ọkàn.
3 Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọÓ le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le
4 Ọkàn ọlọgbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.
5 Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.