14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò óỌlọ́run tí ó dá èkínnínáà ni ó dá ìkejìnítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwáríohun kankan nípa ọjọ́ iwájúu rẹ̀.
15 Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí:Ènìyàn olóòtìítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.
16 Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọtàbí ọlọ́gbọ́n jùlọkí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
17 Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrèÈéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé
18 Ó dára láti mú ọ̀kankí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.
19 Ọgbọ́n máa ń mú kí Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbáraju alákòóṣo mẹ́wàá lọ ní ìlú
20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyétí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.