16 Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọtàbí ọlọ́gbọ́n jùlọkí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
17 Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrèÈéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé
18 Ó dára láti mú ọ̀kankí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.
19 Ọgbọ́n máa ń mú kí Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbáraju alákòóṣo mẹ́wàá lọ ní ìlú
20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyétí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.
21 Má ṣe kíyè sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.
22 Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹpé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmìíràn.