5 Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.
6 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkòni ẹ̀rín òmùgọ̀,Aṣán sì ni eléyìí pẹ̀lú.
7 Ìrẹ́jẹ a máa ṣọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.
8 Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,ṣùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.
9 Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹnítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.
10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti bèèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.
11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún-ìní jẹ́ ohun tí ó dáraó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.