7 Ìrẹ́jẹ a máa ṣọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.
8 Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,ṣùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.
9 Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹnítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.
10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti bèèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.
11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún-ìní jẹ́ ohun tí ó dáraó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.
12 Ọgbọ́n jẹ́ ààbògẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbòṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyípé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá níi.
13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:“Ta ni ó le è toohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”