1 Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fí itará ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa ṣọ tẹ́lẹ̀.
2 Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀;
3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbani-níyànjú, àti ìtùnú.
4 Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ìjọ múlẹ̀.
5 Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa, pẹ̀lúpẹ̀lú láti lè máa sọtẹ́lẹ̀: Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ tóbi jú ẹni ti ń sọ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtúmọ̀, kí ijọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́.
6 Ǹjẹ nísinsìnyìí, ará, bí mo bá wá sí àárin yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmí óò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá iṣọtẹ́lẹ̀, tàbí nipá ẹ̀kọ́?
7 Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìba à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí?