7 Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣaajú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá àyè fún èkejì.
8 Nítorí tí o rí àbùkù lára wọn, ó wí pé,“Kíyèsí i ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí,ti èmi o bá ilé Ísírẹ́lìàti ilé Júdà dá májẹ̀mu títún.
9 Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mútí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá,nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jádekúrò ní Íjíbítì, nítorí wọn kò jẹ́ olótítọ́ sí májẹ̀mú mièmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wíni Olúwa wí.
10 Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lìdá lẹ̀yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn,èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn,èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn,wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.
11 Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀,tàbi olukulùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘mọ Olúwa,’Nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí,láti kékere dé àgbà.
12 Nítorí pé èmi ó ṣáànu fún àìṣódodo wọn,àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àiṣedeede wọn lèmí ki yóò sì rántí mọ́.”
13 Ní èyí tí ó wí pé, Májẹ̀mu títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.