38 Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè! Ṣe ẹ lè mu nínú ago kíkorò tí èmi ó mú tàbí a lè bamitíìsì yín pẹ̀lú irú ìbamitíìsì ìjiyà tí a ó fi bamitíìsì mi?”
39 Àwọn méjèèjì dáhùn pé, “Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó mu ago ti èmi yóò mu, àti bamitíìsímù tí a sí bamitíìsì mi ni a ó fi bamitíìsì yín,
40 ṣùgbọ́n láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ ọ̀sì mi kì ì ṣe ti èmi láti fi fún ni: bí kò ṣe fún àwọn ẹni tí a ti pèṣè rẹ̀ sílẹ̀ fún.”
41 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù béèrè, wọ́n bínú.
42 Nítorí ìdí èyí, Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn.
43 Ṣùgbọ́n láàrin yín ó yàtọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́.
44 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín