42 Nítorí ìdí èyí, Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn.
43 Ṣùgbọ́n láàrin yín ó yàtọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́.
44 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín
45 Nítorí, Èmi, Ọmọ ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àti láti kú fún ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”
46 Wọ́n dé Jẹ́ríkò, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan, Bátíméù, ọmọ Tíméù jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń sagbe.
47 Nígbà tí Bátiméù gbọ́ pé Jésù ti Násárẹ́tì wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jésù ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi.”
48 Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jésù ọmọ Dáfídì ṣàánú fún mi.”