6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì wọ̀nyí sọ ohun tí Jésù ní kí wọ́n sọ. Nítorí náà àwọn ènìyàn náà yọ̀ǹda fún wọn láti mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lọ.
7 Wọ́n mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jésù wá. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì bọ́ ẹ̀wù wọn, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún Jésù láti jókòó lórí rẹ̀.
8 Nígbà náà, púpọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́ àṣọ wọn sójú-ọ̀nà níwájú u rẹ̀. Àwọn mìíràn ju ewéko ìgbẹ́ sílẹ̀.
9 Jésù wà láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn níwájú, lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé,“Hòsánà!”“Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”
10 “Olubùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dáfídì, baba wa!”“Hòsánà lókè ọ̀run!”
11 Jésù wọ Jerúsálémù ó sì lọ sí inú tẹ́ḿpílì. Ó wo ohun gbogbo yíká fínnífínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti sú. Ó padà lọ sí Bẹ́tanì pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.
12 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Bẹ́tanì, ebi ń pa Jésù.