Máàkù 12:1-7 BMY

1 Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ síí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan dá oko àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yì i ká, ó sì gbẹ́ ihò níbi tí omi yóò ti máa jáde fún ìtọ́jú ohun ọ̀gbìn. Níkẹyìn, ó gbé oko fún àwọn olùtọ́jú, ó sì lọ ìrìnàjò tí ó jìnnà.

2 Lákókò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn tí ń tọ́jú oko tí ó fi sílẹ̀, láti gba ìpín tirẹ̀ wá nínú ohun ọ̀gbìn oko náà.

3 Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọnnnì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

4 Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ tí tún rí ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú.

5 Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmiran.

6 “Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkárarẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn àgbẹ̀ náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’

7 “Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọmọ baba olóko, wọ́n sọ fún ara wọn pé, ‘Ọmọ rẹ̀ ló ń bọ̀ yìí. Òun ni yóò jogún oko yìí tí baba rẹ̀ bá kú. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, lẹ́yìn náà oko náà yóò di tiwa.’