37 Níwọ̀n ìgbà tí Dáfídì tìkáraarẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni ó tún ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
38 Ó sì wí fún wọn pé nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ́ra lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́-òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígun rìn kiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọja,
39 àti ibùjókòó ọlá nínú Sínágọ́gù àti ipò ọlá níbi àṣẹ.
40 Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígun fún àsehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”
41 Jésù jókòó kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i.
42 Ṣùgbọn obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ kọ́bọ̀ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdáméjì owó-bàbà kan sínú rẹ̀.
43 Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìì sọ sínú àpótí ìsura ju gbogbo àwọn ìyókù lọ to sọ sínú rẹ lọ.