2 Jésù dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
3 Bí Jésù ti jókòó níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olífì tí ó rékọjá àfonífojì láti Jerúsálémù, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Ańdérù wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkòkọ̀ pé,
4 “Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ḿpílì náà? Kí ni yóò sì jẹ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?”
5 Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tan yín.
6 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ni orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kírísítì,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ́.
7 Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí.
8 Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jin ni ibi púpọ̀. Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú.