Máàkù 13:3-9 BMY

3 Bí Jésù ti jókòó níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olífì tí ó rékọjá àfonífojì láti Jerúsálémù, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Ańdérù wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkòkọ̀ pé,

4 “Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ḿpílì náà? Kí ni yóò sì jẹ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?”

5 Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tan yín.

6 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ni orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kírísítì,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ́.

7 Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí.

8 Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jin ni ibi púpọ̀. Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú.

9 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyè sára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú tẹ́ḿpìlì wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn gómìnà àti níwájú àwọn ọba pẹ̀lú, nítorí tí ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.