44 Ẹnú ya Pílátù láti gbọ́ pé Jésù ti kú. Nítorí náà ó pe balógun-ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jésù ti kú ní tòótọ́.
45 Nígbà tí balógun-ọ̀rún náà sì fún Pílátù ni ìdánilójú pé Jésù ti kú, Pílátù yọ̀ǹda òkú rẹ̀ fún Jóṣẹ́fù.
46 Jóṣẹ́fù sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jésù kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.
47 Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jósè ń wò ó bi Jóṣẹ́fù ti n tẹ́ Jésù sí ibojì.