4 Nígbà náà ni Jésù bèèrè lọ́wọ́ wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.
5 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.
6 Lójúkan-náà, àwọn Farisí jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ ẹ̀yin Hẹ́rọ́dù gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jésù.
7 Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì àti Jùdíà sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
8 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrpyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Jùdíà, Jerúsálémù àti Ìdúmíà, àti láti apákejì odò Jọ́dání àti láti ihà Tírè àti Ṣídónì.
9 Nítorí ẹ̀rọ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ lati sètò ọkọ̀ ojú omi kekere kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn ẹ̀rọ̀ sẹ́yìn.
10 Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló yí i ká, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ọwọ́ kàn án.