6 Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jónà, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ.
7 Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrin ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbà sókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúngbìn náà kò le so èso.
8 Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Ó sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
9 Jésù sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́”
10 Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léérèè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?”
11 Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láàyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.
12 Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé,“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”