2 Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí sínágọ́gù láti kọ́ àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́, wọ́n wí pé,“Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí? Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, ti irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?
3 À bí kì í ṣe kápẹ́ríta ni? Àbí kì í ṣe ọmọ. Màríà àti arákùnrin Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, Júdásì àti Símónì? Àbí kì í ṣe ẹni ti àwọn arábìnrin rẹ̀ ń gbé àárin wa níhìn ín?” Wọ́n sì kọsẹ̀ lára rẹ̀.
4 Nígbà náà, Jésù wí fún wọn pé, “A máa ń bu ọlá fún wòlíì níbi gbogbo àfi ní ìlú ara rẹ̀ àti láàrin àwọn ìdílé àti àwọn ẹbí òun pàápàá.”
5 Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrin wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn.
6 Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sí àárin àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn.
7 Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì-méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.
8 Òun sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtilẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò, tàbí owó lọ́wọ́.