14 Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹ̀ṣẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká. Àwọn olùkọ́-òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn.
15 Bí Jésù ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i.
16 Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyàn-jiyàn?”
17 Ọkùnrin kan láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́.
18 Àti pé, nígbàkúùgbà tí ó bá mú un, á gbé e sánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ ẹyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”
19 Ó sì dá wọn lóhun, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.”
20 Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan-náà ẹ̀mi náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lulẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófóò lẹ́nu.