3 Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan láyé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀.
4 Nígbà náà ni Èlíjà àti Mósè farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jésù.
5 Pétérù sì wí fún Jesù pé, “Rábì, ó dára fún wa láti máa gbé níhìnín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà.”
6 Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìba sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
7 Ìkuukuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkúùkù náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”
8 Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkan kan mọ́, bí kò ṣe Jésù nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.
9 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ-Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú.