30 Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Gálílì kọjá. Níbẹ̀ ni Jésù ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i.
31 Nítorí o kọ̀ awọn Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, o si wí fun wọn pe, “A o fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn ó sì pa á, lẹ́yìn ìgbà tí a bá sì pa á tan yóò jíǹde ní ijọ́ kẹta.”
32 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ ohun tí ó sọ náà.
33 Wọ́n dé sí Kapanámù. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tan nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?”
34 Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́; nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé ta ni ó ga jùlọ láàrin àwọn?
35 Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.”
36 Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,