32 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ ohun tí ó sọ náà.
33 Wọ́n dé sí Kapanámù. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tan nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?”
34 Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́; nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé ta ni ó ga jùlọ láàrin àwọn?
35 Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.”
36 Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,
37 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gba ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.”
38 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jòhánù, sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwá rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ̀ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ wa.”