7 Ìkuukuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkúùkù náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”
8 Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkan kan mọ́, bí kò ṣe Jésù nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.
9 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ-Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú.
10 Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí.
11 Nísinsìnyìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, èéṣe tí àwọn olùkọ́-ófin ń sọ wí pé, “Èlíjà ní yóò kọ́kọ́ dé.”
12 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni Èlíjà yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò. Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ-Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
13 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Èlíjà ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.”