3 nípa títẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọba Israẹli. Òun náà tilẹ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè oníwà burúkú tí OLUWA lé kúrò lórí ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Israẹli.
4 Ní gbogbo ibi gíga, ati àwọn orí òkè ati abẹ́ gbogbo igi ni Ahasi tií máa rúbọ, tíí sìí sun turari.
5 Resini, ọba Siria, ati Peka, ọba Israẹli, gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó ti Ahasi, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀.
6 Ní àkókò kan náà ni ọba Edomu gba Elati pada, ó sì lé àwọn ará Juda tí wọn ń gbé ibẹ̀, àwọn ará Edomu sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní olónìí.
7 Ahasi ranṣẹ lọ bá Tigilati Pileseri, ọba Asiria, ó ní, “Iranṣẹ ati ọmọ rẹ ni mo jẹ́, nítorí náà, jọ̀wọ́ wá gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọba Siria ati ti Israẹli tí wọ́n gbógun tì mí.”
8 Ahasi kó fadaka ati wúrà tí ó wà ninu ilé OLUWA, ati tinú àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin jọ, ó kó o ranṣẹ sí ọba Asiria.
9 Ọba Asiria gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì gbógun ti Damasku, ó ṣẹgun rẹ̀, ó pa Resini ọba, ó sì kó gbogbo àwọn eniyan ìlú náà lẹ́rú lọ sí Kiri.