9 Ọba Asiria gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì gbógun ti Damasku, ó ṣẹgun rẹ̀, ó pa Resini ọba, ó sì kó gbogbo àwọn eniyan ìlú náà lẹ́rú lọ sí Kiri.
10 Nígbà tí Ahasi lọ pàdé Tigilati Pileseri ọba, ní Damasku, ó rí pẹpẹ ìrúbọ kan níbẹ̀, ó sì ranṣẹ sí Uraya alufaa pé kí ó mọ irú rẹ̀ gan-an láìsí ìyàtọ̀ kankan.
11 Ki Ahasi tó dé, Uraya bá mọ irú pẹpẹ ìrúbọ náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ahasi rán sí i láti Damasku.
12 Nígbà tí Ahasi pada dé, o rí i pé Uraya ti mọ pẹpẹ ìrúbọ náà; ó lọ sí ìdí rẹ̀,
13 ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí rẹ̀. Ó rú ẹbọ ohun mímu, ó sì da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ alaafia rẹ̀ sí ara rẹ̀.
14 Pẹpẹ idẹ tí a ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA wà ní ààrin pẹpẹ tirẹ̀ ati ilé OLUWA. Nítorí náà, Ahasi gbé pẹpẹ idẹ náà sí apá òkè pẹpẹ tirẹ̀.
15 Lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fún Uraya alufaa, ó ní, “Máa lo pẹpẹ ìrúbọ tí ó tóbi yìí fún ẹbọ sísun àárọ̀ ati ẹbọ ohun jíjẹ ìrọ̀lẹ́, ati fún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọba, ati fún ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu ti àwọn eniyan. Kí o sì máa da ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá pa fún ìrúbọ sí orí rẹ̀. Ṣugbọn gbé pẹpẹ ìrúbọ idẹ tọ̀hún sọ́tọ̀ fún mi kí n lè máa lò ó láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ OLUWA.”