5 Hesekaya ní igbagbọ ninu OLUWA Ọlọrun Israẹli. Juda kò sì ní ọba mìíràn tí ó dà bíi rẹ̀, yálà ṣáájú rẹ̀ ni, tabi lẹ́yìn rẹ̀.
6 Ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA, kò yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn ó fi tọkàntọkàn pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose mọ́.
7 OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ó gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria, ó di òmìnira, ó kọ̀ kò sìn ín mọ́.
8 Ó ṣẹgun àwọn ará Filistia, títí dé ìlú Gasa ati agbègbè tí ó yí i ká, ati ilé ìṣọ́ wọn, ati ìlú olódi wọn.
9 Ní ọdún kẹrin tíí Hesekaya jọba, tíi ṣe ọdún keje tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba lórí Israẹli, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti Samaria, ó sì dó tì í.
10 Nígbà tí ó ti di ọdún kẹta tí ó ti dó ti Samaria, ó ṣẹgun rẹ̀. Èyí jẹ́ ọdún kẹfa tí Hesekaya jọba, ati ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba.
11 Ọba Asiria kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria, ó sì kó wọn sí ìlú Hala ati Habori tí ó wà ní agbègbè odò Gosani ati sí àwọn ìlú àwọn ará Media.