7 OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ó gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria, ó di òmìnira, ó kọ̀ kò sìn ín mọ́.
8 Ó ṣẹgun àwọn ará Filistia, títí dé ìlú Gasa ati agbègbè tí ó yí i ká, ati ilé ìṣọ́ wọn, ati ìlú olódi wọn.
9 Ní ọdún kẹrin tíí Hesekaya jọba, tíi ṣe ọdún keje tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba lórí Israẹli, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti Samaria, ó sì dó tì í.
10 Nígbà tí ó ti di ọdún kẹta tí ó ti dó ti Samaria, ó ṣẹgun rẹ̀. Èyí jẹ́ ọdún kẹfa tí Hesekaya jọba, ati ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba.
11 Ọba Asiria kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria, ó sì kó wọn sí ìlú Hala ati Habori tí ó wà ní agbègbè odò Gosani ati sí àwọn ìlú àwọn ará Media.
12 Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n si da majẹmu tí OLUWA bá wọn dá. Wọn kò pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose, iranṣẹ rẹ̀ mọ́, wọn kò sì gbọ́ràn.
13 Ní ọdún kẹrinla tí Hesekaya jọba ní Juda, ni Senakeribu, ọba Asiria, gbógun ti àwọn ìlú olódi Juda, ó sì ṣẹgun wọn.