Àwọn Ọba Keji 4:36-42 BM

36 Lẹ́yìn náà, ó wí fún Gehasi pé kí ó pe obinrin ará Ṣunemu náà wá, Gehasi bá pè é. Nígbà tí obinrin náà dé, Eliṣa wí fún un pé kí ó gba ọmọ rẹ̀.

37 Obinrin náà wólẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú ọmọ rẹ̀, ó sì jáde lọ.

38 Eliṣa dé sí Giligali nígbà tí ìyàn wà ní ilẹ̀ náà. Bí àwọn ọmọ wolii ti jókòó níwájú rẹ̀, ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbé ìkòkò ńlá léná kí ẹ sì se àsáró fún àwọn ọmọ wolii.”

39 Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ náà lọ sí oko láti já ewébẹ̀, ó rí àjàrà tí ó máa ń hù ninu igbó, ó sì ká ninu èso rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó rẹ́ wọn sinu ìkòkò àsáró náà láìmọ̀ ohun tí wọ́n jẹ́.

40 Wọ́n bu oúnjẹ fún àwọn ọmọ wolii láti jẹ. Bí wọ́n ti ń jẹ àsáró náà, wọ́n kígbe pé “Eniyan Ọlọrun, májèlé wà ninu ìkòkò yìí!” Wọn kò sì lè jẹ ẹ́ mọ́.

41 Eliṣa dáhùn, ó ní, “Ẹ bu oúnjẹ díẹ̀ wá.” Ó da oúnjẹ náà sinu ìkòkò, ó sì wí pé, “Bu oúnjẹ fún àwọn ọkunrin náà, kí wọ́n lè jẹun.” Kò sì sí oró májèlé ninu oúnjẹ náà mọ́.

42 Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.”