Àwọn Ọba Keji 4:37-43 BM

37 Obinrin náà wólẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú ọmọ rẹ̀, ó sì jáde lọ.

38 Eliṣa dé sí Giligali nígbà tí ìyàn wà ní ilẹ̀ náà. Bí àwọn ọmọ wolii ti jókòó níwájú rẹ̀, ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbé ìkòkò ńlá léná kí ẹ sì se àsáró fún àwọn ọmọ wolii.”

39 Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ náà lọ sí oko láti já ewébẹ̀, ó rí àjàrà tí ó máa ń hù ninu igbó, ó sì ká ninu èso rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó rẹ́ wọn sinu ìkòkò àsáró náà láìmọ̀ ohun tí wọ́n jẹ́.

40 Wọ́n bu oúnjẹ fún àwọn ọmọ wolii láti jẹ. Bí wọ́n ti ń jẹ àsáró náà, wọ́n kígbe pé “Eniyan Ọlọrun, májèlé wà ninu ìkòkò yìí!” Wọn kò sì lè jẹ ẹ́ mọ́.

41 Eliṣa dáhùn, ó ní, “Ẹ bu oúnjẹ díẹ̀ wá.” Ó da oúnjẹ náà sinu ìkòkò, ó sì wí pé, “Bu oúnjẹ fún àwọn ọkunrin náà, kí wọ́n lè jẹun.” Kò sì sí oró májèlé ninu oúnjẹ náà mọ́.

42 Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.”

43 Ṣugbọn iranṣẹ rẹ̀ wí pé, “Báwo ni n óo ṣe wá gbé èyí kalẹ̀ níwájú ọgọrun-un eniyan láti jẹ?”Eliṣa tún ní, “Kó wọn fún àwọn ọmọkunrin kí wọ́n jẹ ẹ́, nítorí pé OLUWA ní, ‘Wọn yóo jẹ, yóo sì ṣẹ́kù.’ ”