4 Gbogbo wọn jọ lọ, nígbà tí wọ́n dé etí odò Jọdani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé igi.
5 Bí ọ̀kan ninu wọn ti ń gé igi, lójijì, irin àáké tí ó ń lò yọ bọ́ sinu odò. Ó kígbe pé, “Yéè! Oluwa mi, a yá àáké yìí ni!”
6 Eliṣa bèèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?”Ọkunrin náà sì fi ibẹ̀ hàn án. Eliṣa gé igi kan, ó jù ú sinu omi, irin àáké náà sì léfòó lójú omi.
7 Eliṣa pàṣẹ fún un pé, “Mú un.” Ọkunrin náà bá mu irin àáké náà.
8 Ní ìgbà kan tí ọba Siria ń bá ọba Israẹli jagun, ó bá àwọn olórí ogun rẹ̀ gbèrò ibi tí wọn yóo ba sí de àwọn ọmọ ogun Israẹli.
9 Eliṣa ranṣẹ sí ọba Israẹli pé kí ó má ṣe gba ibẹ̀ nítorí pé àwọn ará Siria ba sibẹ.
10 Ọba Israẹli bá ranṣẹ sí àwọn eniyan tí ń gbé ibi tí Eliṣa kilọ̀ fún un nípa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ níí máa ń kìlọ̀ fún ọba Israẹli tí ọba Israẹli sì ń bọ́ kúrò ninu tàkúté ọba Siria. Ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà.