Àwọn Ọba Keji 9:12-18 BM

12 Wọ́n dáhùn pé, “Rárá, a kò mọ̀ ọ́n, sọ fún wa.”Jehu sì dáhùn pé, “Ó sọ fún mi pé OLUWA ti fi òróró yàn mí ní ọba lórí Israẹli.”

13 Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́ aṣọ wọn sílẹ̀ fún un kí ó dúró lé, wọ́n sì fun fèrè pé, “Kabiyesi, Jehu ọba!”

14 Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ mọ́ Joramu. (Ní àkókò yìí Joramu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli ń ṣọ́ Hasaeli ọba Siria ní Ramoti Gileadi;

15 ṣugbọn Joramu ọba ti lọ sí Jesireeli láti tọ́jú ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun Siria.) Jehu sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Bí ẹ bá wà lẹ́yìn mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò ní ìlú láti lọ ròyìn fún wọn ní Jesireeli.”

16 Jehu gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó lọ sí Jesireeli nítorí ibẹ̀ ni Joramu ọba wà, Ahasaya, ọba Juda sì wá bẹ̀ ẹ́ wò níbẹ̀.

17 Ọ̀kan ninu àwọn aṣọ́nà tí ó wà ninu ilé ìṣọ́ ní Jesireeli rí i tí Jehu ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ń bọ̀. Ó sì kígbe pé, “Mo rí àwọn ọkunrin kan tí wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́ ogun bọ̀.”Joramu dáhùn pé, “Rán ẹlẹ́ṣin kan láti bèèrè bóyá alaafia ni.”

18 Ẹlẹ́ṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba wí pé, ṣé alaafia ni?”Jehu dá a lóhùn pé, “Kí ni o ní ṣe pẹlu alaafia? Bọ́ sẹ́yìn mi.” Olùṣọ́ náà wí pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn ṣugbọn kò pada wá.”