18 Ẹlẹ́ṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba wí pé, ṣé alaafia ni?”Jehu dá a lóhùn pé, “Kí ni o ní ṣe pẹlu alaafia? Bọ́ sẹ́yìn mi.” Olùṣọ́ náà wí pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn ṣugbọn kò pada wá.”
19 Wọ́n bá tún rán oníṣẹ́ mìíràn lọ láti bèèrè ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ Jehu. Ó tún dáhùn pé “Kí ni o fẹ́ fi alaafia ṣe? Bọ́ sẹ́yìn mi.”
20 Olùṣọ́ bá tún jíṣẹ́ fun ọba pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣugbọn kò pada.” Ó tún fi kún un pé, “Wọ́n ń wa kẹ̀kẹ́ ogun wọn bíi Jehu, ọmọ Nimṣi, nítorí wọ́n ń wà á pẹlu ibinu.”
21 Joramu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé kẹ̀kẹ́ ogun òun wá, wọ́n sì gbé e wá fún un. Joramu ọba ati Ahasaya, ọba Juda sì jáde lọ pàdé Jehu, olukuluku ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Wọ́n pàdé rẹ̀ ninu oko Naboti ara Jesireeli.
22 Joramu bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni?”Jehu dáhùn pé, “Alaafia ṣe lè wà níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè ati àjẹ́ ìyá rẹ ṣì wà sibẹ.”
23 Joramu bá kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí, Ahasaya!” Ó yí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pada, ó ń sá lọ.
24 Jehu fi gbogbo agbára ta ọfà rẹ̀, ó bá Joramu lẹ́yìn, ó wọ inú ọkàn rẹ̀ lọ, Joramu sì kú sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.