5 Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bá àwọn olórí ogun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ó wí pé, “Balogun, wọ́n rán mi níṣẹ́ sí ọ.”Jehu bá bèèrè pé, “Ta ni ninu wa?”Ọdọmọkunrin náà bá dáhùn pé, “Ìwọ ni, Balogun.”
6 Àwọn mejeeji bá jọ wọ inú yàrá lọ, ọdọmọkunrin wolii náà da òróró sí orí Jehu, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, àwọn eniyan OLUWA.’
7 O óo pa ìdílé oluwa rẹ, Ahabu ọba rẹ́, kí n lè gbẹ̀san lára Jesebẹli fún àwọn wolii mi ati àwọn iranṣẹ mi tí ó pa.
8 Gbogbo ìdílé Ahabu ni yóo ṣègbé, n óo sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin tí wọ́n wà ninu ìdílé náà, ati ẹrú ati ọmọ.
9 N óo ṣe ìdílé Ahabu bí mo ti ṣe àwọn ìdílé Jeroboamu ọmọ Nebati, ati ìdílé Baaṣa ọba, ọmọ Ahija.
10 Ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli, kò sí ẹni tí yóo sin òkú rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ náà tán, ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sá lọ.
11 Nígbà tí Jehu pada sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé kò sí nǹkan? Kí ni ọkunrin bíi wèrè yìí ń wá lọ́dọ̀ rẹ?”Jehu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ọkunrin náà, ati ohun tí ó sọ?”