Nehemaya 12:42-47 BM

42 Ṣemaaya, Eleasari ati Usi, Jehohanani, Malikija, Elamu, ati Eseri. Àwọn akọrin kọrin, Jesirahaya sì ni olórí wọn.

43 Wọ́n ṣe ìrúbọ pataki ní ọjọ́ náà, wọ́n sì yọ̀, nítorí Ọlọrun jẹ́ kí wọ́n yọ ayọ̀ ńlá, àwọn obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wọn náà yọ̀ pẹlu. Àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn réré sì gbúròó igbe ayọ̀ ní Jerusalẹmu.

44 Ní ọjọ́ náà, wọ́n yan àwọn kan láti mójútó àwọn ilé ìṣúra, ati ọrẹ tí àwọn eniyan dájọ, àwọn èso àkọ́so, ati ìdámẹ́wàá, àwọn tí wọ́n yàn ni wọ́n ń mójútó pípín ẹ̀tọ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìlú wọn, bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé òfin. Inú àwọn ará ilẹ̀ Juda dùn pupọ sí àwọn alufaa ati sí àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn.

45 Wọ́n ṣe ìsìn Ọlọrun ati ìsìn ìyàsímímọ́ bí àwọn akọrin ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ṣe, gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi ati ti ọmọ rẹ̀, Solomoni.

46 Nítorí pé látijọ́, ní ìgbà ayé Dafidi ati Asafu, wọ́n ní olórí fún àwọn akọrin, wọ́n sì ní àwọn orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.

47 Nígbà ayé Serubabeli ati Nehemaya, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli a máa fún àwọn akọrin ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà ní ẹ̀tọ́ wọn ojoojumọ, wọn a máa ya ìpín àwọn ọmọ Lefi náà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Lefi náà a sì máa ya ìpín àwọn ọmọ Aaroni sọ́tọ̀.