3 Tobaya ará Amoni náà sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun orí ohun tí wọ́n mọ, tí wọn ń pè ní odi olókùúta, wíwó ni yóo wó o lulẹ̀!”
4 Mo bá gbadura pé, “Gbọ́, Ọlọrun wa, nítorí pé wọ́n kẹ́gàn wa. Yí ẹ̀gàn wọn pada lé wọn lórí, kí o sì fi wọ́n lé alágbèédá lọ́wọ́ ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ.
5 Má mójú fo àìdára wọn, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò ninu àkọsílẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ, nítorí pé wọ́n ti mú ọ bínú níwájú àwọn tí wọn ń mọ odi.”
6 Bẹ́ẹ̀ ni, à ń mọ odi náà, a mọ ọ́n já ara wọn yípo, ó sì ga dé ìdajì ibi tí ó yẹ kí ó ga dé, nítorí pé àwọn eniyan náà ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn.
7 Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ati Tobaya ati àwọn ará Arabu, ati àwọn ará Amoni, ati àwọn ará Aṣidodu, gbọ́ pé a ti ń ṣe àtúnṣe àwọn odi Jerusalẹmu ati pé a ti ń dí àwọn ihò ibẹ̀, inú bí wọn gidigidi.
8 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ láti wá gbógun ti Jerusalẹmu kí wọ́n lè dá rúkèrúdò sílẹ̀.
9 Ṣugbọn a gbadura sí Ọlọrun wa, a sì yan àwọn olùṣọ́ láti máa ṣọ́ ibẹ̀ tọ̀sán-tòru.