8 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ láti wá gbógun ti Jerusalẹmu kí wọ́n lè dá rúkèrúdò sílẹ̀.
9 Ṣugbọn a gbadura sí Ọlọrun wa, a sì yan àwọn olùṣọ́ láti máa ṣọ́ ibẹ̀ tọ̀sán-tòru.
10 Àwọn ará Juda bẹ̀rẹ̀ sí kọrin pé,“Agbára àwa tí à ń ṣe iṣẹ́ ń dín kù,iṣẹ́ sì tún pọ̀ nílẹ̀;ǹjẹ́ a ó lè mọ odi náà mọ́ báyìí?”
11 Àwọn ọ̀tá wa sì wí pé, “Wọn kò ní mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní rí wa títí tí a óo fi dé ọ̀dọ̀ wọn, tí a óo pa wọ́n, tí iṣẹ́ náà yóo sì dúró.”
12 Ṣugbọn àwọn Juu tí wọn ń gbé ààrin wọn wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ọpọlọpọ ìgbà, wọ́n sì sọ fún wa pé, “Láti gbogbo ilẹ̀ wọn ni wọn yóo ti dìde ogun sí wa.”
13 Nítorí náà mo fi àwọn eniyan ṣọ́ gbogbo ibi tí odi ìlú bá ti gba ibi tí ilẹ̀ ti dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, mo yan olukuluku ní ìdílé ìdílé, wọ́n ń ṣọ́ odi ní agbègbè wọn pẹlu idà, ọ̀kọ̀, ati ọrun wọn.
14 Mo dìde, mo wò yíká, mo bá sọ fún àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan yòókù pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. Ẹ ranti OLUWA tí ó tóbi tí ó sì bani lẹ́rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arakunrin yín, ati àwọn ọmọkunrin yín, àwọn ọmọbinrin yín, ati àwọn iyawo yín, ati àwọn ilé yín.”