Nehemaya 8:12-18 BM

12 Gbogbo àwọn eniyan náà lọ, wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì fi oúnjẹ ati ohun mímu ranṣẹ sí àwọn eniyan wọn, wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá nítorí pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yé wọn.

13 Ní ọjọ́ keji, àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, péjọ sọ́dọ̀ Ẹsira, akọ̀wé, kí ó lè la ọ̀rọ̀ òfin náà yé wọn.

14 Wọ́n rí i kà ninu òfin tí OLUWA fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ̀dún oṣù keje,

15 ati pé kí wọ́n kéde rẹ̀ ní gbogbo àwọn ìlú wọn ati ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ lọ sí orí àwọn òkè, kí ẹ sì mú àwọn ẹ̀ka igi olifi wá, ati ti paini, ati ti mitili, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka àwọn igi mìíràn láti fi pàgọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀.”

16 Àwọn eniyan náà jáde, wọ́n sì lọ wá imọ̀ ọ̀pẹ ati ẹ̀ka igi wá, wọ́n sì pàgọ́ fún ara wọn, kaluku pàgọ́ sí orí ilé, ati sí àgbàlá ilé wọn ati sí àgbàlá ilé Ọlọrun pẹlu, wọ́n pàgọ́ sí ìta Ẹnubodè Omi ati sí ìta Ẹnubodè Efuraimu.

17 Gbogbo àpéjọ àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú pa àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn. Láti ìgbà ayé Joṣua ọmọ Nuni, títí di àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kò pàgọ́ bẹ́ẹ̀ rí, gbogbo wọn sì yọ ayọ̀ ńlá.

18 Lojoojumọ, láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ tí àsè náà parí, ni wọ́n ń kà ninu ìwé òfin. Wọ́n ṣe àjọ̀dún àsè náà fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n pe àpéjọ tí ó lọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí ó wà ninu àkọsílẹ̀.