2 Dafidi bá mú àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji; Ahinoamu ará Jesireeli, ati Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli lọ́wọ́ lọ.
3 Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ pẹlu, ati gbogbo ìdílé wọn, wọ́n sì ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè Heburoni.
4 Lẹ́yìn náà, àwọn ará Juda wá sí Heburoni, wọ́n fi òróró yan Dafidi ní ọba wọn. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Jabeṣi Gileadi ni wọ́n sin òkú Saulu,
5 ó ranṣẹ sí wọn pé, “Kí OLUWA bukun yín nítorí pé ẹ ṣe olóòótọ́ sí Saulu ọba wa, ẹ sì sin òkú rẹ̀.
6 Kí OLUWA fi ìfẹ́ ńlá ati òdodo rẹ̀ hàn fun yín. Èmi náà yóo ṣe yín dáradára, nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí.
7 Nítorí náà, ẹ mọ́kàn gírí kí ẹ sì ṣe akin; nítorí pé Saulu, oluwa yín ti kú, àwọn eniyan Juda sì ti fi òróró yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.”
8 Abineri ọmọ Neri, tíí ṣe balogun àwọn ọmọ ogun Saulu, gbé Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu sá lọ sí Mahanaimu ní òdìkejì odò Jọdani.