Samuẹli Keji 23:3-9 BM

3 Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀,Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé,‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba,tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun,

4 a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu,ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu;ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’

5 “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun,nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo,majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀.Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi.Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi.

6 Ṣugbọn àwọn tí wọn kò mọ Ọlọrundàbí igi ẹ̀gún tí a gbé sọnù,kò sí ẹni tí ó lè fi ọwọ́ lásán gbá wọn mú.

7 Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀,láti fi wọ́n jóná patapata.”

8 Orúkọ àwọn ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n jẹ́ akọni ati akikanju nìwọ̀nyí: Ekinni ni, Joṣebu-Baṣebeti, ará Takimoni, òun ni olórí ninu “Àwọn Akọni Mẹta,” ó fi ọ̀kọ̀ bá ẹgbẹrin (800) eniyan jà, ó sì pa gbogbo wọn ninu ogun kan ṣoṣo.

9 Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn.