Samuẹli Keji 4:1-7 BM

1 Nígbà tí Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu gbọ́ pé wọ́n ti pa Abineri ní Heburoni, ẹ̀rù bà á gidigidi, ìdààmú sì bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

2 Iṣiboṣẹti ní àwọn ìjòyè meji kan, tí wọ́n jẹ́ aṣaaju fún àwọn tí wọ́n máa ń dánà káàkiri. Orúkọ ekinni ni Baana, ti ekeji sì ni Rekabu, ọmọ Rimoni, ará Beeroti, ti ẹ̀yà Bẹnjamini. (Ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ka Beeroti kún.)

3 Àwọn ará Beeroti ti sá lọ sí Gitaimu, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní olónìí.

4 Jonatani ọmọ Saulu ní ọmọkunrin kan, tí ó yarọ, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mẹfiboṣẹti. Ọmọ ọdún marun-un ni, nígbà tí wọ́n mú ìròyìn ikú Saulu ati ti Jonatani wá, láti ìlú Jesireeli; ni olùtọ́jú rẹ̀ bá gbé e sá kúrò. Ibi tí ó ti ń fi ìkánjú gbé ọmọ náà sá lọ, ó já ṣubú, ó sì fi bẹ́ẹ̀ yarọ.

5 Ní ọjọ́ kan, Rekabu ati Baana, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti, gbéra, wọ́n lọ sí ilé Iṣiboṣẹti, wọ́n débẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán, ní àkókò tí Iṣiboṣẹti ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́.

6 Oorun ti gbé obinrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, tí ń fẹ́ ọkà lọ́wọ́ lọ, ó sùn lọ fọnfọn. Rekabu ati Baana bá rọra yọ́ wọlé.

7 Nígbà tí wọ́n wọlé, wọ́n bá a níbi tí ó sùn sí lórí ibùsùn ninu yàrá rẹ̀, wọ́n lù ú pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà rìn.