26 àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.
27 Nítorí náà a rán Juda ati Sila, láti fẹnu sọ ohun kan náà tí a kọ sinu ìwé fun yín.
28 Ẹ̀mí Mímọ́ ati àwa náà pinnu pé kí á má tún di ẹrù tí ó wúwo jù le yín lórí mọ́, yàtọ̀ sí àwọn nǹkan pataki wọnyi:
29 kí ẹ má jẹ ẹran tí a fi rúbọ sí oriṣa; kí ẹ má jẹ ẹ̀jẹ̀; kí ẹ má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí ẹ má ṣe àgbèrè. Bí ẹ bá takété sí àwọn nǹkan wọnyi, yóo dára. Ó dìgbà o!”
30 Nígbà tí àwọn tí a rán kúrò, wọ́n dé Antioku, wọ́n pe gbogbo ìjọ, wọ́n fún wọn ní ìwé náà.
31 Nígbà tí wọ́n kà á, inú wọn dùn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó wà ninu rẹ̀.
32 Juda ati Sila, tí wọ́n jẹ́ wolii fúnra wọn, tún fi ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ gba ẹgbẹ́ onigbagbọ náà níyànjú, wọ́n tún mú wọn lọ́kàn le.