22 Nígbà tí ó gúnlẹ̀ ní Kesaria, ó lọ kí ìjọ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Antioku.
23 Ó dúró níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó bá tún kúrò, ó la agbègbè Galatia ati ti Firigia já, ó ń mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn le.
24 Ọkunrin Juu kan, ará Alẹkisandria, dé sí Efesu. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Apolo. Ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ̀, ó sì mọ Ìwé Mímọ́ pupọ.
25 A ti fi ọ̀nà Oluwa kọ́ ọ, a máa sọ̀rọ̀ pẹlu ìtara; a sì máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jesu ní àkọ́yé. Ṣugbọn ìrìbọmi tí Johanu ṣe nìkan ni ó mọ̀.
26 Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà ninu ilé ìpàdé àwọn Juu. Nígbà tí Pirisila ati Akuila gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un, wọ́n túbọ̀ fi ọ̀nà Ọlọrun yé e yékéyéké.
27 Nígbà tí ó fẹ́ kọjá lọ sí Akaya, àwọn onigbagbọ ní Efesu fún un ní ìwúrí, wọ́n kọ ìwé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Akaya pé kí wọ́n gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Nígbà tí Apolo dé Akaya, ó wúlò lọpọlọpọ fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ níbẹ̀.
28 Bí ó bá bá àwọn Juu jiyàn níwájú gbogbo àwùjọ, a máa borí wọn, kedere ni ó ń fihàn láti inú Ìwé Mímọ́ pé Jesu ni Mesaya.