2 Nígbà tí wọ́n pe Paulu, Tatulu bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́. Ó ní:“Fẹliksi ọlọ́lá jùlọ, à ń jọlá alaafia tí ẹ mú wá lọpọlọpọ, a sì ń gbádùn oríṣìíríṣìí àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe lọ́tùn-ún lósì fún àwọn ọmọ ilẹ̀ wa.
3 Ọjọ́ iwájú ni ẹ̀ ń rò tí ẹ fi ń ṣe èyí nígbà gbogbo. A dúpẹ́ pupọ lọ́wọ́ yín.
4 N kò fẹ́ gbà yín ní àkókò títí, mo bẹ̀ yín kí ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbọ́ ohun tí a níláti sọ ní ṣókí.
5 Onijamba eniyan ni ọkunrin yìí; rúkèrúdò ni ó ń dá sílẹ̀ láàrin àwọn Juu ní gbogbo àgbáyé. Ọ̀gá ni ninu ẹgbẹ́ àwọn Nasarene.
6 A ká a mọ́ ibi tí ó ti fẹ́ mú ohun ẹ̀gbin wọ inú Tẹmpili, a bá mú un. [A fẹ́ jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí òfin wa.
7 Ṣugbọn ọ̀gágun Lisia wá fi ipá gbà á kúrò lọ́wọ́ wa, ni ó bá mú un lọ.
8 Òun ni ó pàṣẹ pé kí àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án wá siwaju yín.] Bí ẹ bá wádìí lẹ́nu òun fúnrarẹ̀, ẹ óo rí i pé òtítọ́ ni gbogbo ẹjọ́ rẹ̀ tí a fi sùn yín.”