5 Ọkunrin náà bá ń wò wọ́n, ó ń retí pé wọn yóo fún òun ní nǹkan.
6 Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.”
7 Ó bá fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó gbé e dìde. Lẹsẹkẹsẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ọrùn-ẹsẹ̀ rẹ̀ bá mókun.
8 Ó bá fò sókè, ó dúró, ó sì ń rìn. Ó bá tẹ̀lé wọn wọ inú Tẹmpili; ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọrun.
9 Gbogbo àwọn eniyan rí i tí ó ń rìn, tí ó ń yin Ọlọrun.
10 Wọ́n ṣe akiyesi pé ẹni tí ó ti máa ń jókòó ṣagbe lẹ́nu Ọ̀nà Dáradára Tẹmpili ni. Ẹnu yà wọ́n, wọ́n ta gìrì sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà.
11 Bí ọkunrin náà ti rọ̀ mọ́ Peteru ati Johanu, gbogbo àwọn eniyan sáré pẹlu ìyanu lọ sọ́dọ̀ wọn ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí à ń pè ní ti Solomoni.